Ọmọ bibi ni ewu púpọ̀, nitori eyi ni Yorùbá fi ma nki “ìyá ọmọ kú ewu”. Ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ tàbi ìkómọ, Bàbá, Ìyá, ẹbi àti ọ̀rẹ́ òbí ọmọ tuntun á fi ìdùnnú hàn nipa ṣíṣe ọpẹ́ pataki fún Ọlọrun
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi ti òbí lò lati fi ẹmi imõre hàn.
ENGLISH TRANSLATION
Child birth is fraught with danger, as a result, Yoruba people often greet the mother of a new born, “well done for escaping the danger”. On the day of the naming ceremony or child dedication, both the father, mother, family and friends of the new baby’s parent would show their gratitude by giving thanks to God.
See below some of the names that parents give to show their gratitude:
Orúkọ lẹkun rẹrẹ/Full name | Orúkọ ni kúkúrú/ Short Form |
English meaning |
Díẹ̀kọ́lọpẹmisoluwa | Díẹ̀kọ́ | My gratitude to God is not in small measure |
Inúmidùnsólú | Midùn | I am joyful in God |
Kárebàmi | Káre | Weldone Father |
Modúpẹ́ | Dúpẹ́ | I give thanks |
Modúpẹ́ọlá | Dúpẹ́ | I am grateful for this wealth |
Mofiyinfólú/Mofiyinólúwa | Fiyin | I give praise to God |
Mofògofólú | Fògo | I glorify God |
Momõreolú | Mõre | I appreciate God’s goodness |
Moṣọpẹ́fólú | Ṣọpẹ́ | I am thankful to God |
Moyọ̀sọ́rẹolúwa | Moyọ̀/Ọrẹ | I rejoice in God’s kindness |
Olúwatóyìn | Toyin | God is worthy of praise |
Olúwaṣeun | Ṣeun | Thank God |
Ọpẹ́mipọ̀ | Ọpẹ́ | My gratitude is much |
Ọpẹ́olú | Ọpẹ́/Olú | Praise God |
Ọpẹ́yẹmi | Yẹmi | I deserve to give thanks |
Ṣògofólú | Fólú | Give God the glory |
Tolúlọpẹ́ | Tolú | To God be the praise |
Originally posted 2014-06-27 12:10:46. Republished by Blog Post Promoter